Sáàmù 89:48-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

48. Ta ni yóò wà láàyè tí kò ní rí ìkú Rẹ̀?Ta lo lé sa kúrò nínú agbára isà-òkú?

49. Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àtijọ́ wà,tí ìwọ ti fi òtítọ́ Rẹ̀ búra fún Dáfídì?

50. Rántí, Olúwa, bí àti ń gan àwọn ìránṣẹ́ Rẹ;bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,

51. Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá Rẹ gàn, Olúwa,tí wọn gan ipaṣẹ̀ Ẹni àmì òróró Rẹ.

52. Olùbùkún ní Olúwa títí láé.Àmín àti Àmín.

Sáàmù 89