Sáàmù 89:38-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti sá tì, ìwọ sì kórìíra;ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró Rẹ.

39. Ìwọ tì sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ Rẹ di òfo;ìwọ tàbùkù adé Rẹ nínú ilẹ

40. Ìwọ tí wo gbogbo àwọn odi Rẹ̀ìwọ sọ ibi gíga Rẹ̀ di ahoro.

41. Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;o ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé e Rẹ̀

42. Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá Rẹ̀ sókè;ìwọ mú gbogbo ọ̀tá Rẹ̀ yọ̀.

43. Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà Rẹ̀ padà,ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.

44. Ìwọ ti mú ògo Rẹ̀ kùnà,ìwọ si wó ìtẹ́ Rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.

45. Ìwọ ti gé ọjọ́ èwé Rẹ̀ kúrú;ìwọ si fi ìtìjú bò ó

46. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?Tí ìwọ ó ha fi ara Rẹ pamọ́ títí láé?Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú Rẹ yóò máa jó bí iná?

Sáàmù 89