22. Àwọn ọ̀tá kí yóò borí Rẹ̀,àwọn ènìyàn búburú kì yóò Rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23. Èmi yóò run àwọn ọ̀tá Rẹ níwájú Rẹèmi yóò lu àwọn tí ó kóríra Rẹ bolẹ̀
24. Òtítọ́ mi àti ìdúróṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú Rẹàti ní orúkọ mi ní a ó gbé ìwo Rẹ ga.
25. Èmi o gbé ọwọ́ Rẹ lórí òkunàti ọwọ́ ọ̀tún Rẹ lórí àwọn odo ńlá
26. Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ní bàbá mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27. Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mí,Ẹni gíga jù àwọn ọba ayé.