Sáàmù 89:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀,tí ó ń rìn Olúwa nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ.

16. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,wọn ń yin òdodo Rẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;nípa ojúrere ni ìwọ wá ń ṣògo.

18. Nítorí tí Olúwa ni asà wa,ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

19. Nígbà náà ní ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran sí àwọn olótítọ́ Rẹ, wí pé:“èmi tí gbé adé kálẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,èmi ti gbé ẹni tí a yan láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.

Sáàmù 89