Sáàmù 84:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ;wọn o máa yìn ọ́ títí láé.

5. Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹàwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

6. Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọwọn sọ ọ́ di kàngaàkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;

7. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipátítí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì.

Sáàmù 84