Sáàmù 69:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbàmí, Ọlọ́run,nítorí omi tí kún dé ọrùn mi.

2. Mo ń rì nínú ìrà jínjìn,níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.Mo ti wá sínú omi jínjìn;ìkún omi bò mí mólẹ̀.

3. Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,nígbà ti èmi dúró de Ọlọ́run mi

4. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìíwọn ju irun orí mi; lọpúpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,àwọn tí ń wá láti pa mí runA fi ipá mú miláti san ohun tí èmi kò jí.

5. Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú Rẹ.

Sáàmù 69