Sáàmù 65:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ni Síónì;sì ọ ni a o mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

2. Ìwọ tí o ń gbọ́ àdúrà,gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ Rẹ.

3. Ọ̀ràn àìṣedédé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò

4. Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàntí o mú wa láti máa gbé àgọ́ Rẹ!A tẹ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé Rẹ,ti tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ.

Sáàmù 65