Sáàmù 64:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́nGbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.

9. Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rùwọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́runwọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10. Jẹ́ kí Olódodo kí o yọ̀ nínú Olúwayóò sì rí ààbò nínú Rẹ̀Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ni àyà yóò máa yìn ín.

Sáàmù 64