Sáàmù 64:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Wọ́n gbìmọ̀ àìsòdodo, wọn wí pé,“A wa ti parí èrò tí a gbà tán”lóòtọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

7. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.

8. Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́nGbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.

9. Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rùwọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́runwọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10. Jẹ́ kí Olódodo kí o yọ̀ nínú Olúwayóò sì rí ààbò nínú Rẹ̀Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ni àyà yóò máa yìn ín.

Sáàmù 64