1. Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mipa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá
2. Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburúkúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
3. Wọn pọ́n ahọ́n wọn bí idàwọn sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
4. Wọ́n tafà ní kọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:wọ́n tafà sí lojijì, wọn kò sì bẹ̀rù.