Sáàmù 139:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ojú Rẹ̀ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé:àti nínú ìwé Rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí,ní ojojumọ́ ni a ń dá wọn,nígbà tí ọ̀kan wọn kò tí i sí.

17. Ọlọ́run, ìrò inú Rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,iye wọn ti pọ̀ tó!

18. Èmi ibá kà wọ́n, wọ́n jù iyanrin lọ ní iye:nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ Rẹ̀ ṣíbẹ̀

19. Ọlọ́run ibá jẹ pa àwọn ènìyàn búburú ní tòótọ́;nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹ̀jẹ̀.

20. Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,àwọn ọ̀tá Rẹ ń pe orúkọ Rẹ ní aṣán!

21. Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò korìíra àwọn tó korìíra Rẹ?Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?

22. Èmi korìíra wọn ní àkótán;èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.

23. Ọlọ́run, wádíì mi, kí ó sì mọ ọkàn mí;dán mi wò, kí ó sì mọ ìrò inú mi

Sáàmù 139