Sáàmù 119:121-133 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

121. Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.

122. Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú:má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

123. Ojú mi kùnà, fún wí wo ìgbàlà Rẹ,fún wíwo ìpinu òdodo Rẹ.

124. Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹkí o sì kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

125. Èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ; ẹ fún mi ní òyekí èmi lè ní òye òfin Rẹ

126. Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;nítorí òfin Rẹ ti fọ́.

127. Nítorí èmi fẹ́ràn àsẹ Rẹju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,

128. Nítorí èmi kíyèsí gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ Rẹ̀,èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

129. Òfin Rẹ̀ ìyanu ni:nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

130. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;ó fi òye fún àwọn òpè.

131. Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,nítorí èmi fojú sọ́nà sí ṣsẹ Rẹ.

132. Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọntí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ.

133. Fi ìsísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ,má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

Sáàmù 119