Sáàmù 104:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìwọ gbé òpin tí wọn kò le kọjá Rẹ̀ kálẹ̀;láéláé ní wọ́n kò ní lé bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.

10. Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;tí ó ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11. Wọn fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omiàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òùngbẹ wọn.

12. Àwọn ẹyẹ ojú òfurufu tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omiwọn ń kọrin láàrin àwọn ẹ̀ka.

13. Ó bú omi rìn àwọn òkè láti iyẹ̀wù Rẹ̀ wá;a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èṣo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

14. Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹàti àwọn ewébẹ fún ènìyàn láti lòkí ó le mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:

15. Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,òróró láti mú ojú Rẹ̀ tan,àti àkàrà láti ra ọkàn Rẹ̀ padà.

16. Àwọn igi Olúwa ni a bomi rin dáradára,Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn.

17. Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọnbí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀.

18. Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro.

Sáàmù 104