7. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ: “Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀.”
8. Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ.
9. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”
10. Kì sì íṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa;
11. Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, (kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kòse ti ẹni tí ńpeni;)