8. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí àyè ṣíṣẹ onírúurú ìfẹ́kúfẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú.
9. Èmi sì ti wà láàyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú.
10. Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá.
11. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí àyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin se ikú pa mi.
12. Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.
13. Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.
14. Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
15. Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń se. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ se gan an n kò se é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kóríra ni mo ń se.