11. A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:“ ‘Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,’ ni Olúwa wí‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”
12. Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
13. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín.
14. Bí ẹni tí ó wà nínú Jésù Olúwa, mo mọ̀ dájú gbangba pé kò sí oùnjẹ tó jẹ́ àìmọ́ nínú ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkẹ́ni ba kà á sí àìmọ́, òun ni ó se àìmọ́ fún.