11. Níti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa.
12. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gangan nínú àdúrà.
13. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò íṣe.
14. Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè.
15. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ má bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkùn, ẹ má bá wọn sọkún.
16. Ẹ má wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe ronú ohun gíga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.
17. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn.
18. Bí ó le ṣe, bí ó ti wà ní ipa ti yín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.