Òwe 31:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ta ni ó le rí aya oníwà rere?Ó níye lórí ju iyùn lọ

11. ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ púpọ̀ nínú rẹ̀kò sì sí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

12. Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibiní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13. Ó sa aṣọ irun àgùtàn olówùú àti ọ̀gbọ̀Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

14. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn

15. Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀.

Òwe 31