Òwe 30:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọ̀rọ̀ Ágúrì ọmọ Jákè, ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Ítíélì, sí Ítíélì àti sí Úkálì:

2. “Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;N kò ní òye ènìyàn.

3. Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́ntàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì

4. Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?Sọ fún mi bí o bá mọ̀.

5. “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;oun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn

6. Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.

7. “Ohun méjì ni mo ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú:

8. Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan,

9. Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹkí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’Tàbí kí ń di òtòsì kí ń sì jalèkí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.

10. “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹ́ èpè lé ọ. Ìwọ yóò sì jìyà rẹ̀.

Òwe 30