Òwe 26:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí i asínwín ti ń juọfà àti ọfà tí ń ṣekú pani

19. ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹtí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”

20. Láìsí igi, iná yóò kúláì sí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.

21. Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.

22. Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlèwọn a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.

23. Bí èédú lára ìkòkò, bẹ́ẹ̀ niẹnu tí ó mú ṣáṣá pẹ̀lú ọkàn búburú.

Òwe 26