15. Àyà ọmọdé ni ìwà-wèrè dì sí;ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
16. Ẹni tó ń ni talákà lára láti ní ọrọ̀,tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
17. Dẹtí rẹ sílẹ̀,kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
18. Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;nígbà tí a sì pèṣè wọn tán ní ètè rẹ.
19. Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà níti Olúwa,èmi fi hàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
20. Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradárasí ọ níti ìmọ̀ràn àti níti ẹ̀kọ́,
21. Kí ó lè mú ọ mọ dídájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?
22. Má ṣe ja talákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ talákà:bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè:
23. Nítorí Olúwa yóò gbéjà wọn,yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.