Òwe 19:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12. Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13. Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

Òwe 19