Òwe 12:19-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ètè tí ń sòótọ́ yóò wà láéláéṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.

20. Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburúṣùgbọ̀n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.

21. Ibi kì í ṣubú lu Olódodo ráráṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.

22. Olúwa kóìríra ètè tí ń parọ́ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn Olóòótọ́.

23. Ènìyàn Olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.

24. Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jọbaṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí sínsìnrú.

25. Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodòṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.

26. Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn sìnà.

27. Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.

Òwe 12