Oníwàásù 7:14-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò óỌlọ́run tí ó dá èkínnínáà ni ó dá ìkejìnítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwáríohun kankan nípa ọjọ́ iwájúu rẹ̀.

15. Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.

16. Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọtàbí ọlọ́gbọ́n jùlọkí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?

17. Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrèÈéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé

18. Ó dára láti mú ọ̀kankí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.

19. Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú

20. Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

21. Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.

22. Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹpé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn.

23. Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọgbọ́n”ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.

24. Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?

25. Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀,láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́nàti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwàbúburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

Oníwàásù 7