Oníwàásù 2:20-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìṣimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn.

21. Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.

22. Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn?

23. Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìṣinmi ní alẹ́. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú.

24. Ènìyàn kò le è ṣe ohun kóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run.

25. Nítorí wí pé láìsí Ọlọ́run, ta ni ó le è jẹ tàbí ki o rí ìgbádùn?

26. Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ni ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹlẹ́ṣẹ̀, o fún-un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun-ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí o tẹ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, aṣán ni, ó dàbí ẹni a gbìyànjú àti mú.

Oníwàásù 2