Oníwàásù 12:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gígaàti ti ìfarapa ní ìgboro;nígbà tí igi álímọ́ǹdì yóò tannáàti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọtí ìfẹ́ kò sì ní ru ṣókè mọ́nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayétí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

6. Rántí rẹ̀—kí okùn fàdákà tó já,tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;kí ìṣa tó fọ́ níbi ìṣun,tàbí kí àyíká-kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

7. Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà rí,tí ẹ̀mí yóò sì padà ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

Oníwàásù 12