Oníwàásù 10:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Bí ejò bá sán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

12. Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.

13. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìṣínwín búburú.

14. Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ta ni ó le è ṣọ fún-un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

15. Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá lágbarakò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìgboro.

16. Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìranṣẹ́ rẹ̀àti tí àwọn ọmọ aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.

Oníwàásù 10