Oníwàásù 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Oníwàásù, ọmọ Dáfídì, ọba Jérúsálẹ́mù:

2. “Aṣán! Aṣán!”ni oníwàásù wí pé“Aṣán pátapáta!Gbogbo rẹ̀ aṣán ni”

3. Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

4. Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

5. Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ.

Oníwàásù 1