1. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Dánì dé Bááṣébà, àti láti ilẹ̀ Gílíádì jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ ṣíwájú Olúwa ni Mísípà.
2. Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì dúró ní ipò wọn ní àpèjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn.
3. (Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù ti gòkè lọ sí Mísípà). Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.”
4. Ará Léfì náà, ọkọ obìrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀.
5. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gíbíà lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú.
6. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí-ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbégbé ìní Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.
7. Nísinsinyìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”
8. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnìkankan nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀.
9. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò se sí Gíbíà ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa.
10. A ó ò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti ọgọ́rùn ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”
11. Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì para pọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.
12. Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárin yín?
13. Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gíbíà yìí wá fún wa, kí àwa lé pa kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì.”Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì.
14. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gíbíà láti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.
15. Ní ẹṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ àwọn ará Bẹ́ńjámínì kó ẹgbàá mẹ́talá (26,000) àwọn ọmọ ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gíbíà.
16. Ní àárin àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára débi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàṣé (wọ́n jẹ́ ata má tàṣe).
17. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, yàtọ̀ sí àwọn ará Bẹ́ńjámínì, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.