15. Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú náà láti wọ̀ ṣíbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí.
16. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Éfúráímù, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gíbíà (ibẹ̀ ni àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko.
17. Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìnàjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?”
18. Ọmọ Léfì náà dá a lóhùn pé, “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbégbé tí ó sápamọ́ ní àwọn òkè Éfúráímù níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsìn yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀.
19. Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ-èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.”
20. “Mo kí ọ kú ààbọ̀ sí ilé mi,” ni ìdáhùn ọkùnrin arúgbó náà. “Èmi yóò pèṣè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ìta.”
21. Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹṣe wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu.
22. Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Bélíálì kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kún; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.”