Ọbadáyà 1:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

8. Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n Édómù run,àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Ísọ̀?

9. A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Témánì,gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Ísọ̀ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

10. Nítorí ìwà ipá sí Jákọ́bù arákùnrin rẹ,ìtìjú yóò bò ọ,a ó sì pa ọ run títí láé.

11. Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apákan,ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹtí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jérúsálẹ́mù,ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

Ọbadáyà 1