4. Nígbà tí ọdún Júbélì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ babańlá wọn.”
5. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìrán Jóṣẹ́fù ń ṣọ tọ̀nà.
6. Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣélófíhádì: Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.
7. Kò sí ogún kan ní Ísírẹ́lì tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ babańlá wọn pamọ́.
8. Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.