8. Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì,
9. Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.
10. “ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù.
11. Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn.