5. Níbẹ̀ ni yóò ti padà, papọ̀ mọ́ odò Éjíbítì, tí yóò sì parí ní òpin Òkun.
6. “ ‘Ìhà ìwọ̀ oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà-ìwọ̀ oòrùn:
7. “ ‘Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì
8. Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì,
9. Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.
10. “ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù.