31. Nígbà náà Mósè àti Élíásárì àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.
32. Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (675,000) ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn.
33. Ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (72,000) màlúù
34. ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
35. Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún, (32,000) ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.
36. Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́:ẹgbàá méjìdínláàdọ́san (337,500) ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àgùntàn.
37. Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn;
38. ẹgbọ̀rọ̀ màlúù jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún, (36,000) tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàdọ́rin (72);
39. kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún, ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, (30,500) tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta; (61).
40. Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n. (32)