39. Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Léfì tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá (22,000).
40. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.
41. Kí o sì gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa.”
42. Mósè sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.
43. Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).
44. Olúwa tún sọ fún Mósè pé,