Nọ́ḿbà 24:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:

5. “Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jákọ́bù,àti ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!

6. “Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde,gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,gẹ́gẹ́ bí igi òpépé tí ó wà lẹ́bá odò.

7. Omi yóò sàn láti inú garawa:èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.“Ọba wọn yóò ga ju Ágágì lọ;ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

Nọ́ḿbà 24