9. Láti ṣónṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀ èdè.
10. Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bùtàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì?Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́,kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn!”
11. Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀ta mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”
12. Ó sì dáhùn wí pé, “Sé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”
13. Nígbà náà Bálákì sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”
14. Ó sì lọ sí pápá Ṣóímù ní orí òkè Písígà, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.