1. Bálámù sọ́ wí pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.”
2. Bálákì ṣe bí Bálámù ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
3. Nígbà náà Bálámù sọ fún Bálákì pé, “Dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn, mí màá sọ fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.