Nọ́ḿbà 22:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. rán oníṣẹ́ pé Bálámù ọmọ Béórì, tí ó wà ní Pétórì, ní ẹ̀bá odò ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Bálákì sọ pé:“Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Éjíbítì; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.

6. Nísinsìnyìí wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”

7. Olórí àwọn Móábù àti Mídíánì sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Bálámù, wọ́n sọ nǹkan tí Bálákì sọ fún wọn.

8. “Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí” Bálámù sọ fún un pé, “Èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí Olúwa bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Móábù dúró sọ́dọ̀ rẹ̀.

9. Ọlọ́run tọ Bálámù wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?”

10. Bálámù sọ fún Ọlọ́run pé, “Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé:

11. ‘Ènìyàn tí ó jáde láti Éjíbítì wá bo ojú ayé. Nísinsin yìí wá kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá màá le bá wọn jà èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”

Nọ́ḿbà 22