Nọ́ḿbà 15:29-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Òfin kan náà ló wà fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, yálà ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò tí ń gbé láàrin yín.

30. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀-ọ́n-mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Olúwa, a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀

31. Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀.’ ”

32. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísirẹ́lì wà nínú ihà, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi ní ọjọ́ Ísínmì.

33. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣa igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Árónì àti ṣíwájú gbogbo ìjọ ènìyàn;

34. Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.

35. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Kíkú ni ọkùnrín náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sọ ọ́ lókúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

36. Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Nọ́ḿbà 15