8. Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà.
9. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”
10. Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fara hàn ní Àgọ́ Ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
11. Olúwa sọ fún Mósè pé: “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrin wọn?
12. Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”
13. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára Írẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrin wọn.