Nọ́ḿbà 10:26-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Págíélì ọmọ Ókíránì ni ìpín ti ẹ̀yà Ásérì,

27. Áhírà ọmọ Énánì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Náfítanì;

28. Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

29. Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì.”

30. Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

31. Mósè sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú ihà, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa.

32. Bí o bá báwa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

33. Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí Ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn.

34. Ìkúùkù Olúwa wà lórí wọn lọ́sán nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

Nọ́ḿbà 10