Nehemáyà 11:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù.

15. Láti inú àwọn ọmọ Léfì:Ṣémáyà ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíyà ọmọ Búnì;

16. Ṣábétaì àti Jóṣábádì, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;

Nehemáyà 11