Mátíù 9:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbà tí Jésù sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dà.” A sì mú obìnrin náà lára dà ni wákàtí kan náà.

23. Nígbà tí Jésù sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afọnfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń paríwó.

24. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà.

Mátíù 9