37. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Nóà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn yóò sì rí.
38. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Nóà fi bọ́ sínú ọkọ̀.
39. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn.
40. Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a yóò mú ẹnì kan, a ó sì fi ẹnì kejì sílẹ̀.
41. Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ́ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹnì kejì sílẹ̀.
42. “Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé.
43. Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀.
44. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúra-sílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ-Eènìyàn yóò jẹ́.
45. “Ǹjẹ́ olóòótọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́?
46. Alábùkún fún ni ọmọ-ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe.
47. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní.
48. Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú, tí ó sì ń wí fún ara rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’
49. Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.
50. Nígbà náà ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò rétí.