42. Jésù wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé:“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,ni ó di pàtàkì igun ilé;Iṣẹ́ Olúwa ni èyí,ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?
43. “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn ẹlòmíràn tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.
44. Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”