Máàkù 9:33-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Wọ́n dé sí Kapanámù. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”

34. Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé ta ni ó ga jùlọ láàrin àwọn?

35. Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”

36. Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

37. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gba ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”

38. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa.”

39. Jésù sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi.

40. Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa

41. Lóòótọ́ ni mo sọ fún ún yín bí ẹnikẹ́ni bá fún un yín ní ife omi kan nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kírísítì, dájúdájú ẹni náà kì yóò sọ èrè rẹ̀ nù bí ó ti wù kí ó rí.

42. “Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú òkun.

43. Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o gbé títí ayé àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ọwọ́ kan ju kí a gbé ọ sínú iná àjóòkú ọ̀run àpáàdì pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì.

44. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nàá kì í kú

45. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnú, ó sàn kí ó di agẹ́sẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹṣẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì.

46. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nàá kì í sì í ku

Máàkù 9