Máàkù 6:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí àárin àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn.

7. Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì-méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.

8. Òun sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtilẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò, tàbí owó lọ́wọ́.

9. Wọn kò tilẹ̀ gbodọ̀ mú ìpàrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́.

10. Jésù wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe ṣípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà.

Máàkù 6