Máàkù 14:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

12. Ní ọjọ́ kìnínní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèṣè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àṣè ìrékọjá?”

13. Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Máàkù 14